The Diamond Daystar
1 min readNov 12, 2021

--

Ẹ̀DÁ ADAMỌ

Àwọn ẹlẹ́ṣìn kiristiteni ń pé ara wọn ní ọmọ Ọlọhun
Nígbàtí àwọn ẹlẹ́ṣìn musulumi ní ẹrú Ọlọ́run ni àwọn ń se
Láì wá òpó lọ òòró, Eléyìí túmò sí pé ìṣẹ̀dá Ọlọrun ni gbogbo wa
Ní tòótọ, elédùmarè l'o ní agbára láti ṣe dá
Agbára lati fi èmí fún
Agbára láti ṣe bí ó ṣe wù lai si ẹni tí ó bií léèrè
Nínú agbára yìí ni ó ti fún ọmọ ádámọ̀

Lára agbára tí Ọlọhun fún ọmọ ènìyàn ni agbára láti hun
Láti se ẹ̀dá nnkan jáde láti inú ohun tí ó ti wa tẹ́lẹ̀
Agbára láti fúnrúgbìn àti láti ka irúgbìn
Agbára láti ronú kí a sì ṣe ẹ̀dá ohun tí a rò
Ìyàlẹ́nu lọ je nítorí wípé ilokulo ni ọmọ adamọ ń lo agbára yii
A kò le mọyì ohun tí a kò jìyà fún
Bóyá ìdí ti ọmọ adamọ fi fẹẹ sọ ara wọn di Ọlọrun nìyí
Tí wón ń wá ọ̀nà gbogbo láti sọ èrò burúkú inú wọn di mimu ṣe
Owuu, ọmọ ádámò! Kí lóde tí ò ń gbìn ẹgún si ori ibùsùn rẹ?

©The Diamond Daystar

--

--

The Diamond Daystar

The Diamond Daystar is a storyteller who loves to share messages of peace, love and health. She creates content around mental health and psychological issues.